1 Kíróníkà 16:31 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 31 Kí ọ̀run yọ̀, kí inú ayé sì dùn;+Ẹ kéde láàárín àwọn orílẹ̀-èdè pé: ‘Jèhófà ti di Ọba!’+ Sáàmù 96:10 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 10 Ẹ kéde láàárín àwọn orílẹ̀-èdè pé: “Jèhófà ti di Ọba!+ Ayé* fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, kò ṣeé ṣí nípò.* Òun yóò dá ẹjọ́ àwọn èèyàn* lọ́nà tí ó tọ́.”+ Sáàmù 97:1 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 97 Jèhófà ti di Ọba!+ Kí inú ayé máa dùn.+ Kí ọ̀pọ̀ erékùṣù máa yọ̀.+ Ìfihàn 19:6 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 6 Mo sì gbọ́ ohun tó dún bí ohùn àwọn tó pọ̀ gan-an àti bí ìró omi tó pọ̀ àti bí ìró àwọn ààrá tó rinlẹ̀. Wọ́n sọ pé: “Ẹ yin Jáà,*+ torí Jèhófà* Ọlọ́run wa, Olódùmarè,+ ti bẹ̀rẹ̀ sí í jọba!+
10 Ẹ kéde láàárín àwọn orílẹ̀-èdè pé: “Jèhófà ti di Ọba!+ Ayé* fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, kò ṣeé ṣí nípò.* Òun yóò dá ẹjọ́ àwọn èèyàn* lọ́nà tí ó tọ́.”+
6 Mo sì gbọ́ ohun tó dún bí ohùn àwọn tó pọ̀ gan-an àti bí ìró omi tó pọ̀ àti bí ìró àwọn ààrá tó rinlẹ̀. Wọ́n sọ pé: “Ẹ yin Jáà,*+ torí Jèhófà* Ọlọ́run wa, Olódùmarè,+ ti bẹ̀rẹ̀ sí í jọba!+