-
1 Tímótì 5:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Kí ẹ kọ orúkọ opó tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò bá dín ní ọgọ́ta (60) ọdún sílẹ̀, tó jẹ́ ìyàwó ọkùnrin kan tẹ́lẹ̀, 10 tí wọ́n mọ̀ sí ẹni tó ń ṣe àwọn iṣẹ́ rere,+ tó bá tọ́ àwọn ọmọ,+ tó bá ṣe aájò àlejò,+ tó bá fọ ẹsẹ̀ àwọn ẹni mímọ́,+ tó bá ṣèrànwọ́ fún àwọn tí ìyà ń jẹ,+ tó sì ń ṣe gbogbo iṣẹ́ rere tọkàntọkàn.
-
-
Títù 2:3-5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Bákan náà, kí àwọn àgbà obìnrin jẹ́ ẹni tó ń bọ̀wọ̀ fúnni, kí wọ́n má ṣe jẹ́ abanijẹ́, kí wọ́n má ṣe jẹ́ ọ̀mùtí, kí wọ́n máa kọ́ni ní ohun rere, 4 kí wọ́n lè máa gba àwọn ọ̀dọ́bìnrin níyànjú* láti nífẹ̀ẹ́ ọkọ wọn, láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn, 5 láti jẹ́ aláròjinlẹ̀, oníwà mímọ́, ẹni tó ń ṣiṣẹ́ ilé,* ẹni rere, tó ń tẹrí ba fún ọkọ,+ kí àwọn èèyàn má bàa sọ̀rọ̀ àbùkù sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
-