Diutarónómì 6:6, 7 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 6 Rí i pé o fi àwọn ọ̀rọ̀ yìí tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sọ́kàn, 7 kí o máa fi kọ́ àwọn ọmọ rẹ+ léraléra,* kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ, nígbà tí o bá ń rìn lójú ọ̀nà, nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.+ Òwe 19:20 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 20 Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ìbáwí,+Kí o lè di ọlọ́gbọ́n ní ọjọ́ ọ̀la rẹ.+ Éfésù 6:1 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 6 Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí yín lẹ́nu+ nínú Olúwa, nítorí èyí jẹ́ òdodo.
6 Rí i pé o fi àwọn ọ̀rọ̀ yìí tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sọ́kàn, 7 kí o máa fi kọ́ àwọn ọmọ rẹ+ léraléra,* kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ, nígbà tí o bá ń rìn lójú ọ̀nà, nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.+