-
Jóòbù 38:8-11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Ta ló sì fi àwọn ilẹ̀kùn sé òkun,+
Nígbà tó tú jáde látinú ikùn,*
9 Nígbà tí mo fi ìkùukùu wọ̀ ọ́ láṣọ,
Tí mo sì fi ìṣúdùdù tó kàmàmà wé e,
10 Nígbà tí mo pààlà ibi tí mo fẹ́ kó dé,
Tí mo sì fi àwọn ọ̀pá àtàwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ sáyè wọn,+
11 Mo sì sọ pé, ‘Ibi tí o lè dé nìyí, má kọjá ibẹ̀;
Ìgbì rẹ tó ń ru sókè kò ní kọjá ibí yìí’?+
-
-
Sáàmù 33:7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Ó gbá omi òkun jọ bí ìsédò;+
Ó fi omi tó ń ru gùdù sínú àwọn ilé ìṣúra.
-