7 Ẹ fún ẹni tí ebi ń pa lára oúnjẹ yín,+
Kí ẹ mú aláìní àti ẹni tí kò rílé gbé wá sínú ilé yín,
Kí ẹ fi aṣọ bo ẹni tó wà ní ìhòòhò tí ẹ bá rí i,+
Kí ẹ má sì kẹ̀yìn sí àwọn èèyàn yín.
8 Ìmọ́lẹ̀ rẹ máa wá tàn bí ọ̀yẹ̀,+
Ìwòsàn rẹ sì máa yára dé.
Òdodo rẹ á máa lọ níwájú rẹ,
Ògo Jèhófà á sì máa ṣọ́ ọ láti ẹ̀yìn.+