3 Ísírẹ́lì nífẹ̀ẹ́ Jósẹ́fù ju gbogbo àwọn ọmọ+ rẹ̀ yòókù lọ torí pé ìgbà tó darúgbó ló bí i, ó sì ṣe aṣọ kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀* fún un. 4 Nígbà tí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ rí i pé bàbá àwọn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ju gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kórìíra rẹ̀, wọn kì í sì í fi sùúrù bá a sọ̀rọ̀.
8 Inú bí Sọ́ọ̀lù gan-an,+ orin yìí sì bà á lọ́kàn jẹ́, ó sọ pé: “Wọ́n fún Dáfídì ní ẹgbẹẹgbàárùn-ún, àmọ́ wọ́n fún mi ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún. Ipò ọba nìkan ló kù kí wọ́n fún un!”+9 Láti ọjọ́ yẹn lọ, ìgbà gbogbo ni Sọ́ọ̀lù ń wo Dáfídì tìfuratìfura.