-
2 Sámúẹ́lì 15:32-34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
32 Nígbà tí Dáfídì dé orí òkè tí àwọn èèyàn ti máa ń forí balẹ̀ fún Ọlọ́run, Húṣáì+ ará Áríkì+ wá pàdé rẹ̀ níbẹ̀, ẹ̀wù rẹ̀ ti ya, iyẹ̀pẹ̀ sì wà lórí rẹ̀. 33 Àmọ́ Dáfídì sọ fún un pé: “Tí o bá bá mi sọdá, wàá di ẹrù sí mi lọ́rùn. 34 Àmọ́ tí o bá pa dà sínú ìlú, tí o sì sọ fún Ábúsálómù pé, ‘Ìránṣẹ́ rẹ ni mí, Ọba. Ìránṣẹ́ bàbá rẹ ni mí tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí, ìránṣẹ́ rẹ ni mo jẹ́,’+ ìgbà náà ni wàá lè bá mi sọ ìmọ̀ràn Áhítófẹ́lì di asán.+
-
-
Òwe 22:29Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 Ǹjẹ́ o ti rí ọkùnrin tó já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀?
Yóò dúró níwájú àwọn ọba;+
Kò ní dúró níwájú àwọn èèyàn yẹpẹrẹ.
-