-
1 Sámúẹ́lì 16:18, 19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Ọ̀kan lára àwọn ẹmẹ̀wà* sọ pé: “Wò ó! Mo ti rí bí ọ̀kan lára àwọn ọmọ Jésè ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ṣe ń ta háàpù dáadáa, onígboyà ni, jagunjagun tó lákíkanjú sì ni.+ Ó mọ̀rọ̀ọ́ sọ, ó rẹwà,+ Jèhófà sì wà pẹ̀lú rẹ̀.”+ 19 Ni Sọ́ọ̀lù bá rán àwọn òjíṣẹ́ sí Jésè pé: “Fi Dáfídì ọmọ rẹ tó wà pẹ̀lú agbo ẹran ránṣẹ́ sí mi.”+
-