2 “Wò ó, mo ti yan* Bẹ́sálẹ́lì+ ọmọ Úráì ọmọ Húrì látinú ẹ̀yà Júdà.+3 Màá fi ẹ̀mí Ọlọ́run kún inú rẹ̀, màá fún un ní ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ nípa onírúurú iṣẹ́ ọnà,
16 Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí,+ ó sì wúlò fún kíkọ́ni,+ fún bíbáni wí, fún mímú nǹkan tọ́,* fún títọ́nisọ́nà nínú òdodo,+17 kí èèyàn Ọlọ́run lè kúnjú ìwọ̀n dáadáa, kó sì lè gbára dì pátápátá fún gbogbo iṣẹ́ rere.
17 Àmọ́, ọgbọ́n tó wá láti òkè á kọ́kọ́ jẹ́ mímọ́,+ lẹ́yìn náà, ó lẹ́mìí àlàáfíà,+ ó ń fòye báni lò,+ ó ṣe tán láti ṣègbọràn, ó máa ń ṣàánú gan-an, ó sì ń so èso rere,+ kì í ṣe ojúsàájú,+ kì í sì í ṣe àgàbàgebè.+