-
Jẹ́nẹ́sísì 13:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Ábúrámù wá sọ fún Lọ́ọ̀tì+ pé: “Jọ̀ọ́, kò yẹ kí ìjà wáyé láàárín èmi àti ìwọ àti láàárín àwọn tó ń da ẹran mi àti àwọn tó ń da ẹran rẹ, torí arákùnrin ni wá. 9 Ṣebí gbogbo ilẹ̀ ló wà níwájú rẹ yìí? Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lọ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Tí o bá lọ sí apá òsì, èmi á lọ sí apá ọ̀tún; àmọ́ tí o bá lọ sí apá ọ̀tún, èmi á lọ sí apá òsì.”
-
-
Òwe 25:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Má fi ìkánjú gbé ọ̀rọ̀ lọ sílé ẹjọ́,
Àbí kí lo máa ṣe tí ọmọnìkejì rẹ bá kàn ọ́ lábùkù?+
-