-
2 Sámúẹ́lì 19:25-27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Nígbà tó dé sí* Jerúsálẹ́mù láti pàdé ọba, ọba bi í pé: “Kí ló dé tí o ò fi bá mi lọ, Méfíbóṣétì?” 26 Ó fèsì pé: “Olúwa mi ọba, ìránṣẹ́ mi+ ló tàn mí. Nítorí ìránṣẹ́ rẹ sọ pé, ‘Jẹ́ kí n di ohun tí wọ́n fi ń jókòó mọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mi,* kí n lè gùn ún, kí n sì bá ọba lọ,’ nítorí arọ+ ni ìránṣẹ́ rẹ. 27 Àmọ́, ó sọ̀rọ̀ èmi ìránṣẹ́ rẹ láìdáa fún ọba.+ Ṣùgbọ́n olúwa mi ọba dà bí áńgẹ́lì Ọlọ́run tòótọ́, torí náà, ohun tó bá dára lójú rẹ ni kí o ṣe.
-
-
Òwe 25:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Má fi ìkánjú gbé ọ̀rọ̀ lọ sílé ẹjọ́,
Àbí kí lo máa ṣe tí ọmọnìkejì rẹ bá kàn ọ́ lábùkù?+
-