14 Èyí ni ogún tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà ní ilẹ̀ Kénáánì, èyí tí àlùfáà Élíásárì àti Jóṣúà ọmọ Núnì àtàwọn olórí agbo ilé àwọn ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún wọn pé kí wọ́n jogún.+ 2 Kèké ni wọ́n fi pín ogún+ fún ẹ̀yà mẹ́sàn-án àtààbọ̀ náà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ nípasẹ̀ Mósè.+