5 Àmọ́ ẹ sọ pé, ‘Ẹnikẹ́ni tó bá sọ fún bàbá tàbí ìyá rẹ̀ pé: “Ẹ̀bùn tí mo yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run ni ohunkóhun tí mo ní tó lè ṣe yín láǹfààní,”+ 6 kò yẹ kó bọlá fún bàbá rẹ̀ rárá.’ Ẹ ti wá sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di èyí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nítorí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ yín.+