ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 37:9-11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Lẹ́yìn ìyẹn, ó tún lá àlá míì, ó sì rọ́ ọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀, ó ní: “Mo tún lá àlá míì. Lọ́tẹ̀ yìí, oòrùn àti òṣùpá àti ìràwọ̀ mọ́kànlá (11) ń tẹrí ba fún mi.”+ 10 Ó rọ́ ọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, bàbá rẹ̀ sì bá a wí, ó ní: “Kí ni ìtúmọ̀ àlá tí o lá yìí? Ṣé èmi àti ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ yóò wá máa tẹrí ba mọ́lẹ̀ fún ọ ni?” 11 Àwọn arákùnrin rẹ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí í jowú rẹ̀,+ àmọ́ bàbá rẹ̀ fi ọ̀rọ̀ náà sọ́kàn.

  • Òwe 14:30
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 30 Ìbàlẹ̀ ọkàn ń mú kí ara lókun,*

      Àmọ́ owú dà bí àìsàn tó ń mú kí egungun jẹrà.+

  • Ìṣe 17:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 Àmọ́ inú bí àwọn Júù,+ wọ́n kó àwọn ọkùnrin burúkú kan jọ tí wọ́n jẹ́ aláìríkan-ṣèkan ní ibi ọjà, wọ́n di àwùjọ onírúgúdù, wọ́n sì dá ìdàrúdàpọ̀ sílẹ̀ nínú ìlú náà. Wọ́n ya wọ ilé Jásónì, wọ́n ń wá ọ̀nà láti mú Pọ́ọ̀lù àti Sílà wá fún àwùjọ náà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́