-
Nọ́ńbà 25:6-8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Ìgbà yẹn gan-an ni ọmọ Ísírẹ́lì kan wá mú obìnrin+ Mídíánì kan wá sí tòsí ibi tí àwọn èèyàn rẹ̀ wà, níṣojú Mósè àti gbogbo àpéjọ Ísírẹ́lì, nígbà tí wọ́n ń sunkún ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 7 Nígbà tí Fíníhásì+ ọmọ Élíásárì ọmọ àlùfáà Áárónì rí i, ojú ẹsẹ̀ ló dìde láàárín àpéjọ náà, ó sì mú ọ̀kọ̀* kan dání. 8 Ló bá tẹ̀ lé ọkùnrin Ísírẹ́lì náà wọnú àgọ́, ó sì gún àwọn méjèèjì ní àgúnyọ, ó gún ọkùnrin Ísírẹ́lì náà àti obìnrin náà níbi ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀. Bí àjàkálẹ̀ àrùn tó kọ lu àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe dáwọ́ dúró+ nìyẹn.
-
-
1 Sámúẹ́lì 15:22, 23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Sámúẹ́lì wá sọ pé: “Ṣé àwọn ẹbọ sísun àti ẹbọ+ máa ń múnú Jèhófà dùn tó kéèyàn ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà? Wò ó! Ṣíṣe ìgbọràn sàn ju ẹbọ,+ fífi etí sílẹ̀ sì sàn ju ọ̀rá+ àgbò; 23 nítorí ẹ̀ṣẹ̀ kan náà ni ìṣọ̀tẹ̀+ àti iṣẹ́ wíwò+ jẹ́, ọ̀kan náà sì ni kíkọjá àyè jẹ́ pẹ̀lú lílo agbára abàmì àti ìbọ̀rìṣà.* Nítorí o ti kọ ọ̀rọ̀ Jèhófà,+ òun náà ti kọ̀ ọ́ ní ọba.”+
-