-
2 Àwọn Ọba 5:20-22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Géhásì,+ ìránṣẹ́ Èlíṣà èèyàn Ọlọ́run tòótọ́+ sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: ‘Ṣé bí ọ̀gá mi á ṣe jẹ́ kí Náámánì ará Síríà+ yìí lọ láìgba ohun tó mú wá nìyẹn? Bí Jèhófà ti wà láàyè, màá sá tẹ̀ lé e, màá sì gba nǹkan kan lọ́wọ́ rẹ̀.’ 21 Torí náà, Géhásì sá tẹ̀ lé Náámánì. Nígbà tí Náámánì rí i pé ẹnì kan ń sáré tẹ̀ lé òun, ó sọ̀ kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ láti pàdé rẹ̀, ó sì sọ pé: “Ṣé àlàáfíà ni?” 22 Ó fèsì pé: “Àlàáfíà ni. Ọ̀gá mi ló rán mi, ó ní, ‘Wò ó! Àwọn ọ̀dọ́kùnrin méjì lára àwọn ọmọ wòlíì ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sọ́dọ̀ mi láti agbègbè olókè Éfúrémù. Jọ̀ọ́, fún wọn ní tálẹ́ńtì fàdákà kan àti ìpààrọ̀ aṣọ méjì.’”+
-
-
Jeremáyà 17:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
Wọ́n á fi í sílẹ̀ ní ọ̀sán gangan ayé rẹ̀,
Ní ìkẹyìn, á wá hàn pé òmùgọ̀ ni.”
-