-
Oníwàásù 2:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Lẹ́yìn náà, mo sọ lọ́kàn mi pé: “Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí òmùgọ̀ ló máa ṣẹlẹ̀ sí èmi náà.”+ Kí wá ni èrè ọgbọ́n tí mo gbọ́n ní àgbọ́njù? Mo sì sọ lọ́kàn mi pé: “Asán ni èyí pẹ̀lú.” 16 Nítorí a kì í rántí ọlọ́gbọ́n tàbí òmùgọ̀ títí lọ.+ Bó pẹ́ bó yá, a ò ní rántí ẹnikẹ́ni mọ́. Báwo sì ni ọlọ́gbọ́n ṣe máa kú? Á kú pẹ̀lú àwọn òmùgọ̀.+
-