Òwe 5:3 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 3 Nítorí ètè obìnrin oníwàkiwà* ń kán tótó bí afárá oyin,+Ọ̀rọ̀* rẹ̀ sì tuni lára ju òróró lọ.+ Òwe 5:14 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 14 Mo ti dé bèbè ìparunNí àárín ìjọ lápapọ̀.”*+ Òwe 7:22, 23 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 22 Lójijì, ó tẹ̀ lé obìnrin náà, bí akọ màlúù tí wọ́n ń mú lọ síbi tí wọ́n ti fẹ́ pa á,Bí òmùgọ̀ tí wọ́n fẹ́ fìyà jẹ nínú àbà,*+23 Títí ọfà fi gún ẹ̀dọ̀ rẹ̀ ní àgúnyọ;Bí ẹyẹ tó kó sínú pańpẹ́, kò mọ̀ pé ẹ̀mí òun máa lọ sí i.+ Òwe 22:14 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 14 Kòtò jíjìn ni ẹnu obìnrin oníwàkiwà.*+ Ẹni tí Jèhófà dá lẹ́bi yóò já sínú rẹ̀.
22 Lójijì, ó tẹ̀ lé obìnrin náà, bí akọ màlúù tí wọ́n ń mú lọ síbi tí wọ́n ti fẹ́ pa á,Bí òmùgọ̀ tí wọ́n fẹ́ fìyà jẹ nínú àbà,*+23 Títí ọfà fi gún ẹ̀dọ̀ rẹ̀ ní àgúnyọ;Bí ẹyẹ tó kó sínú pańpẹ́, kò mọ̀ pé ẹ̀mí òun máa lọ sí i.+