- 
	                        
            
            1 Àwọn Ọba 9:17-19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        17 Sólómọ́nì kọ́* Gésérì, Bẹti-hórónì Ìsàlẹ̀,+ 18 Báálátì+ àti Támárì ní aginjù, ó kọ́ wọn sórí ilẹ̀ náà, 19 Sólómọ́nì tún kọ́ gbogbo àwọn ìlú tó ń kó nǹkan pa mọ́ sí, àwọn ìlú kẹ̀kẹ́ ẹṣin,+ àwọn ìlú àwọn agẹṣin àti ohunkóhun tó wu Sólómọ́nì láti kọ́ sí Jerúsálẹ́mù, sí Lẹ́bánónì àti sí gbogbo ilẹ̀ tó ń ṣàkóso lé lórí. 
 
-