-
1 Sámúẹ́lì 13:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Ni mo bá sọ fún ara mi pé, ‘Àwọn Filísínì máa wá gbéjà kò mí ní Gílígálì, mi ò sì tíì wá ojú rere Jèhófà.’* Ìdí nìyẹn tí mo fi rí i pé ó pọn dandan kí n rú ẹbọ sísun náà.”
13 Ni Sámúẹ́lì bá sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Ìwà òmùgọ̀ lo hù. O ò ṣègbọràn sí àṣẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ pa fún ọ.+ Ká ní o ṣe bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ì bá fìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì títí láé.
-