-
Diutarónómì 29:22, 23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 “Tí ìran àwọn ọmọ yín lọ́jọ́ iwájú àti àwọn àjèjì tó wá láti ọ̀nà jíjìn bá rí àwọn àjálù tó bá ilẹ̀ náà, àwọn ìyọnu tí Jèhófà mú wá sórí rẹ̀, 23 ìyẹn, imí ọjọ́, iyọ̀ àti iná, kí wọ́n má bàa fúnrúgbìn kankan sí gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ tàbí kí irúgbìn hù níbẹ̀, kí ewéko kankan má sì hù níbẹ̀, bí ìparun Sódómù àti Gòmórà,+ Ádímà àti Sébóímù,+ tí Jèhófà fi ìbínú àti ìrunú rẹ̀ pa run,
-
-
Jeremáyà 45:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 “Kí o sọ fún un pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Wò ó! Ohun tí mo ti kọ́ ni màá ya lulẹ̀, ohun tí mo sì ti gbìn ni màá fà tu, ìyẹn gbogbo ilẹ̀ náà.+
-