ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 29:22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Torí náà, ohun tí Jèhófà, ẹni tó ra Ábúráhámù pa dà,+ sọ fún ilé Jékọ́bù nìyí:

      “Ojú ò ní ti Jékọ́bù mọ́,

      Ojú rẹ̀ ò sì ní funfun mọ́.*+

  • Àìsáyà 54:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Má bẹ̀rù,+ torí ojú ò ní tì ọ́;+

      Má sì jẹ́ kí ìtìjú bá ọ, torí o ò ní rí ìjákulẹ̀.

      Torí o máa gbàgbé ìtìjú ìgbà ọ̀dọ́ rẹ,

      O ò sì ní rántí bí ojú ṣe tì ọ́ nígbà opó rẹ mọ́.”

  • Jóẹ́lì 2:26
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 26 Ó dájú pé ẹ ó jẹ àjẹyó,+

      Ẹ ó sì yin orúkọ Jèhófà Ọlọ́run yín,+

      Ẹni tó ti ṣe ohun ìyanu fún yín;

      Wọn ò ní dójú ti àwọn èèyàn mi mọ́ láé.+

  • Sefanáyà 3:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Ní ọjọ́ yẹn, ojú ò ní tì ọ́

      Nítorí gbogbo ohun tí o ṣe láti fi ṣọ̀tẹ̀ sí mi,+

      Torí nígbà náà, màá mú àwọn agbéraga tó ń fọ́nnu kúrò láàárín rẹ;

      O ò sì ní gbéra ga mọ́ ní òkè mímọ́ mi.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́