- 
	                        
            
            Jeremáyà 31:35, 36Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        35 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, Ẹni tó ń mú kí oòrùn máa tan ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán, Tó sì ṣe òfin* pé kí òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ máa tàn ní òru, Ẹni tó ń ru òkun sókè, tó sì ń mú kí ìgbì rẹ̀ máa pariwo, Ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun:+ 36 “‘Bí àwọn ìlànà yìí bá yí pa dà Nìkan ni àtọmọdọ́mọ Ísírẹ́lì kò fi ní jẹ́ orílẹ̀-èdè níwájú mi mọ́,’ ni Jèhófà wí.”+ 
 
- 
                                        
- 
	                        
            
            Jónà 1:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        4 Lẹ́yìn náà, Jèhófà mú kí ìjì kan tó lágbára jà lórí òkun, ìjì náà sì le débi pé ọkọ̀ náà fẹ́rẹ̀ẹ́ ya. 
 
-