ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 40:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  9 Lọ sórí òkè tó ga,

      Ìwọ obìnrin tó ń mú ìròyìn ayọ̀ wá fún Síónì.+

      Gbé ohùn rẹ sókè tagbáratagbára,

      Ìwọ obìnrin tó ń mú ìròyìn ayọ̀ wá fún Jerúsálẹ́mù.

      Gbé e sókè, má bẹ̀rù.

      Kéde fún àwọn ìlú Júdà pé: “Ọlọ́run yín rèé.”+

  • Náhúmù 1:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Wò ó! Orí àwọn òkè ni ẹsẹ̀ ẹni tó ń mú ìhìn rere wá wà,

      Ẹni tó ń kéde àlàáfíà.+

      Ṣe àwọn àjọyọ̀ rẹ,+ ìwọ Júdà, kí o sì san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ,

      Nítorí ẹni tí kò ní láárí kò tún ní gba àárín rẹ kọjá mọ́.

      Ṣe ni yóò pa run pátápátá.”

  • Ìṣe 8:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Síbẹ̀, àwọn tó ti tú ká ń lọ káàkiri ilẹ̀ náà, wọ́n ń kéde ìhìn rere ọ̀rọ̀ náà.+

  • Róòmù 10:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Báwo ni wọ́n á sì ṣe wàásù láìjẹ́ pé a rán wọn jáde?+ Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Ẹsẹ̀ àwọn tó ń kéde ìhìn rere àwọn ohun rere mà rẹwà o!”+

  • Éfésù 6:14, 15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Nítorí náà, ẹ dúró gbọn-in, kí ẹ fi òtítọ́ di inú yín lámùrè,+ kí ẹ sì gbé àwo ìgbàyà òdodo wọ̀,+ 15 pẹ̀lú ẹsẹ̀ yín tí a wọ̀ ní bàtà, kí ẹ lè fi ìmúratán kéde ìhìn rere àlàáfíà.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́