-
2 Àwọn Ọba 18:13, 14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Ní ọdún kẹrìnlá Ọba Hẹsikáyà, Senakérúbù ọba Ásíríà+ wá gbéjà ko gbogbo ìlú olódi Júdà, ó sì gbà wọ́n.+ 14 Nítorí náà, Hẹsikáyà ọba Júdà ránṣẹ́ sí ọba Ásíríà ní Lákíṣì pé: “Èmi ni mo jẹ̀bi. Má ṣe bá mi jà mọ́, ohunkóhun tí o bá ní kí n san ni màá san.” Ni ọba Ásíríà bá bu ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) tálẹ́ńtì* fàdákà àti ọgbọ̀n (30) tálẹ́ńtì wúrà lé Hẹsikáyà ọba Júdà.
-
-
Àìsáyà 8:7, 8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
Ó máa wá sórí gbogbo ibi tí omi rẹ̀ ń ṣàn gbà,
Ó máa kún bo gbogbo bèbè rẹ̀,
8 Ó sì máa rọ́ gba Júdà kọjá.
-