Àìsáyà 61:6 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 6 Ní tiyín, a ó máa pè yín ní àlùfáà Jèhófà;+Wọ́n á máa pè yín ní òjíṣẹ́ Ọlọ́run wa. Ẹ máa jẹ ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,+Ẹ sì máa fi ògo* wọn yangàn. Hágáì 2:7, 8 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 7 “‘Èmi yóò mi gbogbo orílẹ̀-èdè jìgìjìgì, àwọn ohun iyebíye* nínú gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì wọlé wá;+ èmi yóò sì fi ògo kún ilé yìí,’+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí. 8 “‘Tèmi ni fàdákà, tèmi sì ni wúrà,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.
6 Ní tiyín, a ó máa pè yín ní àlùfáà Jèhófà;+Wọ́n á máa pè yín ní òjíṣẹ́ Ọlọ́run wa. Ẹ máa jẹ ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,+Ẹ sì máa fi ògo* wọn yangàn.
7 “‘Èmi yóò mi gbogbo orílẹ̀-èdè jìgìjìgì, àwọn ohun iyebíye* nínú gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì wọlé wá;+ èmi yóò sì fi ògo kún ilé yìí,’+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí. 8 “‘Tèmi ni fàdákà, tèmi sì ni wúrà,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.