18 Torí náà, ẹ yọ̀, kí inú yín sì máa dùn títí láé torí ohun tí mò ń dá.
Torí wò ó! Mò ń dá Jerúsálẹ́mù láti mú ayọ̀ wá
Àti àwọn èèyàn rẹ̀ láti jẹ́ orísun ìdùnnú.+
19 Inú mi máa dùn nínú Jerúsálẹ́mù, màá sì yọ̀ torí àwọn èèyàn mi;+
A ò ní gbọ́ igbe ẹkún tàbí igbe ìdààmú nínú rẹ̀ mọ́.”+