-
Diutarónómì 28:49-51Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
49 “Jèhófà máa gbé orílẹ̀-èdè kan tó wà lọ́nà jíjìn+ dìde sí ọ, láti ìkángun ayé; ó máa kì ọ́ mọ́lẹ̀ bí ẹyẹ idì+ ṣe ń ṣe, orílẹ̀-èdè tí o ò ní gbọ́+ èdè rẹ̀, 50 orílẹ̀-èdè tí ojú rẹ̀ le gan-an, tí kò ní wo ojú arúgbó, tí kò sì ní ṣojúure sí àwọn ọmọdé.+ 51 Wọ́n á jẹ àwọn ọmọ ẹran ọ̀sìn rẹ àti èso ilẹ̀ rẹ títí wọ́n fi máa pa ọ́ run. Wọn ò ní ṣẹ́ ọkà kankan kù fún ọ àti wáìnì tàbí òróró tuntun, ọmọ màlúù tàbí àgùntàn, títí wọ́n fi máa pa ọ́ run.+
-
-
Jeremáyà 5:17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Wọ́n á jẹ irè oko rẹ àti oúnjẹ rẹ.+
Wọ́n á pa àwọn ọmọkùnrin rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ.
Wọ́n á jẹ àwọn agbo ẹran rẹ àti àwọn ọ̀wọ́ ẹran rẹ.
Wọ́n á jẹ àjàrà rẹ àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ.
Wọ́n á fi idà pa ìlú olódi rẹ tí o gbẹ́kẹ̀ lé run.”
-