29 O máa ń kìlọ̀ fún wọn kí o lè mú wọn pa dà wá sínú Òfin rẹ, síbẹ̀ ṣe ni wọ́n ń kọjá àyè wọn, wọn ò sì fetí sí àwọn àṣẹ rẹ;+ wọ́n ń ṣe ohun tó ta ko ìlànà rẹ, èyí tó máa jẹ́ kẹ́ni tó ba ń pa á mọ́ lè wà láàyè.+ Agídí wọn mú kí wọ́n kẹ̀yìn sí ọ, wọ́n mú kí ọrùn wọn le, wọn ò sì fetí sílẹ̀.