24 Yàtọ̀ síyẹn, Áhásì kó àwọn nǹkan èlò ilé Ọlọ́run tòótọ́ jọ; ó sì gé àwọn nǹkan èlò ilé Ọlọ́run tòótọ́ sí wẹ́wẹ́,+ ó ti àwọn ilẹ̀kùn ilé Jèhófà pa,+ ó sì ṣe àwọn pẹpẹ fún ara rẹ̀ sí gbogbo igun ọ̀nà Jerúsálẹ́mù.
25 Nítorí pé wọ́n ti fi mí sílẹ̀,+ wọ́n sì ń mú ẹbọ rú èéfín sí àwọn ọlọ́run míì láti fi gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wọn mú mi bínú,+ ìbínú mi máa tú jáde bí iná sórí ibí yìí, kò sì ní ṣeé pa.’”+