-
Léfítíkù 2:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 “‘Tí ẹnì* kan bá fẹ́ mú ọrẹ ọkà+ wá fún Jèhófà, kó jẹ́ ìyẹ̀fun tó kúnná, kó da òróró sórí rẹ̀, kó sì fi oje igi tùràrí sórí rẹ̀.+ 2 Kó wá gbé e wá fún àwọn ọmọ Áárónì, tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, kí àlùfáà sì bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun náà tí wọ́n pò mọ́ òróró àti gbogbo oje igi tùràrí rẹ̀, kó sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ bí ọrẹ ìṣàpẹẹrẹ,*+ ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, tó ní òórùn dídùn.*
-