-
Mátíù 4:13-16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Bákan náà, lẹ́yìn tó kúrò ní Násárẹ́tì, ó wá lọ ń gbé ní Kápánáúmù + lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkun ní agbègbè Sébúlúnì àti Náfútálì, 14 kí ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòlíì Àìsáyà lè ṣẹ, ẹni tó sọ pé: 15 “Ìwọ ilẹ̀ Sébúlúnì àti ilẹ̀ Náfútálì, ní ojú ọ̀nà òkun, ní òdìkejì Jọ́dánì, Gálílì àwọn orílẹ̀-èdè! 16 Àwọn èèyàn tó jókòó sínú òkùnkùn rí ìmọ́lẹ̀ tó mọ́lẹ̀ yòò, ní ti àwọn tó jókòó sí agbègbè òjìji ikú, ìmọ́lẹ̀+ tàn sórí wọn.”+
-