28 Nígbà tí Jésù sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí tán, ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé bó ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ya àwọn èrò náà lẹ́nu,+29 torí ṣe ló ń kọ́ wọn bí ẹni tó ní àṣẹ,+ kò kọ́ wọn bí àwọn akọ̀wé òfin wọn.
42 A máa gbé ọbabìnrin gúúsù dìde láti ṣèdájọ́ ìran yìí, ó sì máa dá a lẹ́bi, torí ó wá láti ìkángun ayé kó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n Sólómọ́nì.+ Àmọ́ ẹ wò ó! ohun kan tó ju Sólómọ́nì lọ wà níbí.+