-
1 Sámúẹ́lì 22:18, 19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Ìgbà náà ni ọba sọ fún Dóẹ́gì+ pé: “Ìwọ, lọ pa àwọn àlùfáà náà!” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Dóẹ́gì ọmọ Édómù+ lọ pa àwọn àlùfáà náà fúnra rẹ̀. Ọkùnrin márùnlélọ́gọ́rin (85) tó ń wọ éfódì+ tí a fi aṣọ ọ̀gbọ̀* ṣe ni ó pa lọ́jọ́ yẹn. 19 Ó tún fi idà ṣá àwọn ará Nóbù+ tó jẹ́ ìlú àwọn àlùfáà balẹ̀; ó pa ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdé àti ọmọ jòjòló, akọ màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti àgùntàn, gbogbo wọn ni ó fi idà pa.
-