ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 19:23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 23 Ní ọjọ́ yẹn, ọ̀nà kan máa jáde+ láti Íjíbítì lọ sí Ásíríà. Ásíríà máa wá sí Íjíbítì, Íjíbítì sì máa lọ sí Ásíríà, Íjíbítì àti Ásíríà sì jọ máa sin Ọlọ́run.

  • Àìsáyà 27:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n máa fun ìwo ńlá kan,+ àwọn tó ń ṣègbé lọ ní ilẹ̀ Ásíríà+ àti àwọn tó fọ́n ká ní ilẹ̀ Íjíbítì+ máa wá, wọ́n á sì forí balẹ̀ fún Jèhófà ní òkè mímọ́, ní Jerúsálẹ́mù.+

  • Àìsáyà 35:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  8 Ọ̀nà kan sì máa wà níbẹ̀,+

      Àní, ọ̀nà tí à ń pè ní Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́.

      Aláìmọ́ kò ní gba ibẹ̀ kọjá.+

      Àwọn tó ń rìn lójú ọ̀nà ló wà fún;

      Òmùgọ̀ kankan ò sì ní rìn gbéregbère lọ síbẹ̀.

  • Àìsáyà 40:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  3 Ohùn ẹnì kan ń ké nínú aginjù pé:

      “Ẹ tún ọ̀nà Jèhófà ṣe!*+

      Ẹ la ọ̀nà tó tọ́  + gba inú aṣálẹ̀ fún Ọlọ́run wa.+

  • Àìsáyà 57:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Wọ́n máa sọ pé, ‘Ẹ ṣe ọ̀nà, ẹ ṣe é! Ẹ tún ọ̀nà ṣe!+

      Ẹ mú gbogbo ohun ìdíwọ́ kúrò ní ọ̀nà àwọn èèyàn mi.’”

  • Jeremáyà 31:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 “Ri àwọn àmì ojú ọ̀nà mọ́lẹ̀ fún ará rẹ,

      Ri àwọn òpó àmì mọ́lẹ̀.+

      Fiyè sí òpópónà, ọ̀nà tí o máa gbà.+

      Pa dà, ìwọ wúńdíá Ísírẹ́lì, pa dà wá sí àwọn ìlú rẹ.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́