3 Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ni Ùsáyà+ nígbà tó jọba, ọdún méjìléláàádọ́ta (52) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jekoláyà tó wá láti Jerúsálẹ́mù.+
6 Ó jáde lọ bá àwọn Filísínì jà,+ ó sì fọ́ ògiri Gátì+ àti ògiri Jábínè+ àti ògiri Áṣídódì+ wọlé. Lẹ́yìn náà, ó kọ́ àwọn ìlú sí ìpínlẹ̀ Áṣídódì àti sáàárín àwọn Filísínì.