ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 17:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Ní ọdún kẹsàn-án Hóṣéà, ọba Ásíríà gba Samáríà.+ Ó wá kó àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ní ìgbèkùn+ lọ sí Ásíríà, ó sì mú kí wọ́n máa gbé ní Hálà àti ní Hábórì níbi odò Gósánì+ àti ní àwọn ìlú àwọn ará Mídíà.+

  • Àìsáyà 7:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  8 Torí Damásíkù ni orí Síríà,

      Résínì sì ni orí Damásíkù.

      Kí ọdún márùndínláàádọ́rin (65) tó pé,

      Éfúrémù máa fọ́ túútúú, wọn ò sì ní jẹ́ èèyàn mọ́.+

  • Àìsáyà 28:1, 2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 28 Adé* ìgbéraga* àwọn ọ̀mùtípara Éfúrémù+ gbé

      Àti ìtànná ẹwà ológo rẹ̀ tó ti ń rọ,

      Tó wà ní orí àfonífojì ọlọ́ràá tó jẹ́ ti àwọn tí wáìnì ti kápá wọn!

       2 Wò ó! Jèhófà ní ẹnì kan tó lókun tó sì lágbára.

      Bí ìjì yìnyín tó ń sán ààrá, ìjì apanirun,

      Bí ìjì tó ń sán ààrá tó ń fa àkúnya omi tó bùáyà,

      Ó máa fipá jù ú sílẹ̀.

  • Hósíà 5:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Màá dà bí ọmọ kìnnìún sí Éfúrémù

      Àti bíi kìnnìún* alágbára sí ilé Júdà.

      Èmi fúnra mi á fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, màá sì lọ;+

      Màá gbé wọn lọ, kò sì sí ẹni tó máa gbà wọ́n sílẹ̀.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́