-
2 Kíróníkà 12:2, 3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Ní ọdún karùn-ún Ọba Rèhóbóámù, Ṣíṣákì+ ọba Íjíbítì wá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù, nítorí wọ́n hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà. 3 Ó ní ẹgbẹ̀rún kan ó lé igba (1,200) kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ọ̀kẹ́ mẹ́ta (60,000) àwọn agẹṣin pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun tí kò níye, tí wọ́n bá a wá láti Íjíbítì, ìyẹn àwọn ará Líbíà, Súkímù àti àwọn ará Etiópíà.+
-
-
2 Kíróníkà 16:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Ṣebí àwọn ará Etiópíà àti àwọn ará Líbíà ní àwọn ọmọ ogun tó pọ̀ rẹpẹtẹ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin pẹ̀lú àwọn agẹṣin? Àmọ́ torí pé o gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́.+
-