-
Jeremáyà 8:18, 19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Ẹ̀dùn ọkàn mi kò ṣeé wò sàn;
Ọkàn mi ń ṣàárẹ̀.
19 Igbe ìrànlọ́wọ́ wá láti ilẹ̀ tó jìnnà
Látọ̀dọ̀ ọmọbìnrin àwọn èèyàn mi pé:
“Ṣé kò sí Jèhófà ní Síónì ni?
Àbí ọba rẹ̀ kò sí níbẹ̀ ni?”
“Kí ló dé tí wọ́n fi fi ère gbígbẹ́ wọn mú mi bínú,
Pẹ̀lú àwọn ọlọ́run àjèjì wọn tí kò ní láárí?”
-
-
Jeremáyà 9:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Ká ní orí mi jẹ́ omi,
Tí ojú mi sì jẹ́ orísun omijé!+
Mi ò bá sunkún tọ̀sántòru
Nítorí àwọn èèyàn mi tí wọ́n pa.
-