ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 5:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Wọ́n ní háàpù àti ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín,

      Ìlù tanboríìnì, fèrè àti wáìnì sì wà níbi àsè wọn;

      Àmọ́ wọn ò ronú nípa iṣẹ́ Jèhófà,

      Wọn ò sì rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

  • Àìsáyà 56:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí n mu wáìnì díẹ̀,

      Ẹ sì jẹ́ ká mu ọtí yó.+

      Bí òní ṣe rí ni ọ̀la máa rí, ó tiẹ̀ máa dáa gan-an jù ú lọ!”

  • Émọ́sì 6:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 “Àwọn tó dá ara wọn lójú* ní Síónì gbé!

      Àwọn tí ọkàn wọn balẹ̀ lórí òkè Samáríà,+

      Àwọn olókìkí èèyàn nínú àwọn orílẹ̀-èdè tó gba iwájú,

      Àwọn tí ilé Ísírẹ́lì ń lọ sọ́dọ̀ wọn!

  • Émọ́sì 6:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Wọ́n ń dùbúlẹ̀ sórí àwọn ibùsùn tí wọ́n fi eyín erin ṣe,+ wọ́n sì ń nà gbalaja sórí àga tìmùtìmù,+

      Wọ́n ń jẹ àwọn àgbò inú agbo ẹran àti àwọn ọmọ màlúù* tí wọ́n bọ́ sanra;+

  • Lúùkù 17:27
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 27 wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, à ń fa àwọn obìnrin fún ọkọ, títí di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì,+ Ìkún Omi sì dé, ó pa gbogbo wọn run.+

  • Jémíìsì 5:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 Ẹ ti gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ, ẹ sì ti tẹ́ ara yín lọ́rùn ní ayé. Ẹ ti bọ́ ọkàn yín yó ní ọjọ́ pípa.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́