ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 9:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ilẹ̀ ayé tí à ń gbé;*+

      Yóò dá ẹjọ́ òdodo fún àwọn orílẹ̀-èdè.+

  • Sáàmù 58:10, 11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Olódodo yóò máa yọ̀ nítorí pé ó ti rí ẹ̀san;+

      Ẹ̀jẹ̀ ẹni burúkú yóò rin ẹsẹ̀ rẹ̀ gbingbin.+

      11 Nígbà náà, aráyé á sọ pé: “Dájúdájú, èrè wà fún olódodo.+

      Ní tòótọ́, Ọlọ́run kan wà tó ń ṣe ìdájọ́ ayé.”+

  • Sáàmù 85:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Òtítọ́ yóò rú jáde látinú ilẹ̀,

      Òdodo yóò sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run.+

  • Sáàmù 85:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Òdodo yóò máa rìn níwájú rẹ̀,+

      Yóò sì la ọ̀nà fún ìṣísẹ̀ rẹ̀.

  • Sáàmù 96:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Níwájú Jèhófà, nítorí ó ń bọ̀,*

      Ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé.

      Yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ilẹ̀ ayé tí à ń gbé,*+

      Yóò sì fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn.+

  • Sáàmù 97:2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  2 Ìkùukùu àti ìṣúdùdù tó kàmàmà yí i ká;+

      Òtítọ́ àti ìdájọ́ òdodo ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀.+

  • Àìsáyà 61:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Torí bí ilẹ̀ ṣe ń mú irúgbìn jáde,

      Tí ọgbà sì ń mú kí ohun tí wọ́n gbìn sínú rẹ̀ hù,

      Bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ

      Ṣe máa mú kí òdodo+ àti ìyìn rú jáde+ níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́