-
Àìsáyà 25:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
Ó máa mú ẹ̀gàn àwọn èèyàn rẹ̀ kúrò ní gbogbo ayé,
Torí Jèhófà fúnra rẹ̀ ti sọ ọ́.
-
-
Máàkù 12:26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Àmọ́ ní ti àjíǹde àwọn òkú, ṣé ẹ ò tíì kà á nínú ìwé Mósè ni, nínú ìtàn igi ẹlẹ́gùn-ún, pé Ọlọ́run sọ fún un pé: ‘Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù’?+
-
-
Ìfihàn 20:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Mo rí àwọn òkú, ẹni ńlá àti ẹni kékeré, wọ́n dúró síwájú ìtẹ́ náà, a sì ṣí àwọn àkájọ ìwé sílẹ̀. Àmọ́ a ṣí àkájọ ìwé míì; àkájọ ìwé ìyè ni.+ A fi àwọn ohun tí a kọ sínú àkájọ ìwé náà ṣèdájọ́ àwọn òkú bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn ṣe rí.+ 13 Òkun yọ̀ǹda àwọn òkú tó wà nínú rẹ̀, ikú àti Isà Òkú* yọ̀ǹda àwọn òkú tó wà nínú wọn, a sì ṣèdájọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn ṣe rí.+
-