ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 6:11, 12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Ni mo bá sọ pé: “Títí dìgbà wo, Jèhófà?” Ó dáhùn pé:

      “Títí àwọn ìlú náà fi máa fọ́ túútúú, tí kò sì ní sẹ́ni tó ń gbé ibẹ̀,

      Tí kò ní sẹ́nì kankan nínú àwọn ilé,

      Títí ilẹ̀ náà fi máa pa run, tó sì máa di ahoro;+

      12 Títí Jèhófà fi máa mú àwọn èèyàn jìnnà,+

      Tí gbogbo ilẹ̀ náà á sì di ahoro.

  • Jeremáyà 26:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 “Míkà+ ti Móréṣétì sọ tẹ́lẹ̀ nígbà ayé Hẹsikáyà+ ọba Júdà, ó sì sọ fún gbogbo èèyàn Júdà pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí:

      “Wọ́n á túlẹ̀ Síónì bíi pápá,

      Jerúsálẹ́mù á di àwókù,+

      Òkè Ilé* náà á sì dà bí àwọn ibi gíga nínú igbó.”’*+

  • Ìdárò 2:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  5 Jèhófà ṣe bí ọ̀tá;+

      Ó ti gbé Ísírẹ́lì mì.

      Ó ti gbé gbogbo ilé gogoro rẹ̀ mì;

      Ó ti run gbogbo ibi olódi rẹ̀.

      Ó sì sọ ọ̀fọ̀ àti ìdárò ọmọbìnrin Júdà di púpọ̀.

  • Ìsíkíẹ́lì 36:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 torí náà, ẹ̀yin òkè Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ fún àwọn òkè ńlá àti àwọn òkè kéékèèké nìyí, fún àwọn ìṣàn omi àti àwọn àfonífojì, fún àwọn àwókù tó ti di ahoro+ àti fún àwọn ìlú tí wọ́n pa tì, tí àwọn tó là á já nínú àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká ti kó ní ẹrù, tí wọ́n sì fi ṣe ẹlẹ́yà;+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́