-
2 Àwọn Ọba 16:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Lẹ́yìn náà, Ọba Áhásì lọ pàdé Tigilati-pílésà ọba Ásíríà ní Damásíkù. Nígbà tó rí pẹpẹ tó wà ní Damásíkù, Ọba Áhásì fi àwòrán pẹpẹ náà ránṣẹ́ sí àlùfáà Úríjà, iṣẹ́ ọnà pẹpẹ náà àti bí wọ́n ṣe mọ ọ́n ló wà nínú àwòrán náà.+ 11 Àlùfáà Úríjà+ mọ pẹpẹ+ kan gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìlànà tí Ọba Áhásì fi ránṣẹ́ láti Damásíkù. Àlùfáà Úríjà parí mímọ pẹpẹ náà kí Ọba Áhásì tó dé láti Damásíkù.
-