-
Máàkù 7:6-8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Ó sọ fún wọn pé: “Bí Àìsáyà ṣe sọ tẹ́lẹ̀ nípa ẹ̀yin alágàbàgebè ló rí gẹ́lẹ́, ó kọ ọ́ pé, ‘Àwọn èèyàn yìí ń fi ètè wọn bọlá fún mi, àmọ́ ọkàn wọn jìnnà gan-an sí mi.+ 7 Lásán ni wọ́n ń jọ́sìn mi, torí pé àṣẹ èèyàn ni ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ni.’+ 8 Ẹ pa àṣẹ Ọlọ́run tì, ẹ wá ń rin kinkin mọ́ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn èèyàn.”+
-