-
Jeremáyà 37:7, 8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Ohun tí ẹ máa sọ fún ọba Júdà, tó rán yín wá sọ́dọ̀ mi láti wádìí nìyí: “Wò ó! Àwọn ọmọ ogun Fáráò tó ń bọ̀ wá ràn yín lọ́wọ́ yóò ní láti pa dà sí Íjíbítì, ilẹ̀ wọn.+ 8 Àwọn ará Kálídíà á sì pa dà wá, wọ́n á bá ìlú yìí jà, wọ́n á gbà á, wọ́n á sì dáná sun ún.”+
-