5 Lẹ́yìn náà, ó dùbúlẹ̀, ó sì sùn lọ lábẹ́ igi náà. Àmọ́ lójijì, áńgẹ́lì kan fọwọ́ kàn án,+ ó sì sọ fún un pé: “Dìde, jẹun.”+6 Nígbà tó máa lajú, ó rí búrẹ́dì ribiti kan lórí àwọn òkúta gbígbóná níbi orí rẹ̀ àti ìgò omi. Ó jẹ, ó sì mu, lẹ́yìn náà, ó sùn pa dà.