ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 19:14-19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Hẹsikáyà gba àwọn lẹ́tà náà lọ́wọ́ àwọn òjíṣẹ́ náà, ó sì kà wọ́n. Lẹ́yìn náà, Hẹsikáyà lọ sí ilé Jèhófà, ó sì tẹ́ wọn* síwájú Jèhófà.+ 15 Hẹsikáyà wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà+ níwájú Jèhófà, ó sọ pé: “Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí o jókòó sórí ìtẹ́ lókè* àwọn kérúbù,+ ìwọ nìkan ni Ọlọ́run tòótọ́ lórí gbogbo ìjọba ayé.+ Ìwọ lo dá ọ̀run àti ayé. 16 Fetí sílẹ̀, Jèhófà, kí o sì gbọ́!+ La ojú rẹ,+ Jèhófà, kí o sì rí i! Kí o gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí Senakérúbù fi ránṣẹ́ láti pẹ̀gàn Ọlọ́run alààyè. 17 Jèhófà, òótọ́ ni pé àwọn ọba Ásíríà ti pa àwọn orílẹ̀-èdè àti ilẹ̀ wọn run.+ 18 Wọ́n sì ti ju àwọn ọlọ́run wọn sínú iná, nítorí wọn kì í ṣe ọlọ́run,+ iṣẹ́ ọwọ́ èèyàn ni wọ́n,+ wọ́n jẹ́ igi àti òkúta. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi lè pa wọ́n run. 19 Àmọ́ ní báyìí, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run wa, jọ̀ọ́ gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀, kí gbogbo ìjọba ayé lè mọ̀ pé ìwọ Jèhófà nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́