Sáàmù 30:3 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 3 Jèhófà, o ti gbé mi* sókè látinú Isà Òkú.*+ O mú kí n wà láàyè, o ò sì jẹ́ kí n rì sínú kòtò.*+ Sáàmù 86:13 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 13 Nítorí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o ní sí mi pọ̀,O sì ti gba ẹ̀mí* mi lọ́wọ́ Isà Òkú.*+ Jónà 2:6 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 6 Mo rì wọnú ibú omi lọ sí ìsàlẹ̀ àwọn òkè. Ní ti ilẹ̀ ayé, àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀ wà lórí mi títí láé. Àmọ́, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi gbé mi dìde láàyè látinú kòtò.+
6 Mo rì wọnú ibú omi lọ sí ìsàlẹ̀ àwọn òkè. Ní ti ilẹ̀ ayé, àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀ wà lórí mi títí láé. Àmọ́, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi gbé mi dìde láàyè látinú kòtò.+