-
2 Àwọn Ọba 20:16-18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Àìsáyà wá sọ fún Hẹsikáyà pé: “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà,+ 17 ‘Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀ tí wọ́n máa kó gbogbo ohun tó wà nínú ilé* rẹ àti gbogbo ohun tí àwọn baba ńlá rẹ ti kó jọ títí di òní yìí lọ sí Bábílónì.+ Kò ní ku nǹkan kan,’ ni Jèhófà wí. 18 ‘Wọ́n á mú àwọn kan lára àwọn ọmọ tí o máa bí,+ wọ́n á sì di òṣìṣẹ́ ààfin ní ààfin ọba Bábílónì.’”+
-